III Yemoja
Oju ẹdá ńwòye lori òkun
Oju alárìnká l'ori okun;
T'afà bi Tìmì Àgbálé si àwọ sanma
Ni ibi ti awon ìràwọ yio gbe jabo
Nko sọ àṣírí si eti enikan,
Àyàfi inu iho ilẹ, lati ba fi pamo ni-
Asiri ti mo fi pamo si eti òkun
Wa nrú
Omi funfun kini bi iyọ lori okuta eti okun ati emi,
Ati edé ati ìkarawun
Ti o nrùn bi okun-
Arábìrin inu ibú
Abara rọgbọdọ,
Ti mo bo aṣiri rẹ mọlẹ pelu iyanrin òkun…
Òjò ṣú biribiri l'ori eti okun ti orun npa
Ojo su biribiri lori okunrin ati obirin.
Ó tànmọlẹ
Pelu ìṣírí abo kiniun,
Ó dahun,
Pelu ìtàná ti o wọ bi ẹwu;
Bệni ìjì òkun ntẹlẽ bọwá si bèbè,
Abo kiniun mi,
Ti a de ni ade oṣupa.
Abo kiniun mi pelu ori eyan
Ti a de ni ade Farao.
Awo yèyé Idoto; awo yeye Ọya
Awẹnrẹn Ifá,
Odùṣọ Èlà, iyekan Ẹlẹgbára
Ìrírí rè ko ju iṣẹju akàn lọ-
Ìsáná ti a tan ni iwaju ĕmí ẹfȗfù nla-
Kia mọsa ni iriri yi je pelu jigi ti o yi mi po.
Sinu omi…
Awon iji omi ńwĕ, bi o ti ńrì sinu omi;
Wúrà ti o ńwọmi
Lai ko si eniti ti o le kõ jọ
Yemoja inu ibú,
Eti àṣírí ti hù bi ìwo Àlàdé*.
Emi ti emi si wa dáwà nihin,
Bẹrẹsi ka iyanrin ti òkun gbe wa sihin,
Ka ore rè, oba birin mi.
Sugbon okun ti o ti wẹwó iji mu òjìjí
Wa lati jigi oju rẹ
Ti kǐ se ti olorì mi, bíkòṣe ojiji ti o ti fón ká.
Idi ni yi ti emi fi nka àkókò ni erékùṣù mi
Ti mo nka wakati ti yio gbe
Obabirin mi ti o pònrá padàwá pelu ami angeli ninu afẹfe
No comments:
Post a Comment