Friday, May 19, 2017

USA Africa Dialogue Series - Ewi Igbokegbodo Keji

III Yemoja

Oju ẹdá ńwòye lori òkun

Oju alárìnká l'ori okun;

T'afà bi Tìmì Àgbálé si àwọ sanma

Ni ibi ti awon ìràwọ yio gbe jabo


Nko sọ àṣírí si eti enikan,

Àyàfi inu iho ilẹ, lati ba fi pamo ni-

Asiri ti mo fi pamo si eti òkun


Wa nrú

Omi funfun kini bi iyọ lori okuta eti okun ati emi,

Ati edé ati ìkarawun

Ti o nrùn bi okun-

Arábìrin inu ibú

Abara rọgbọdọ,

Ti mo bo aṣiri rẹ mọlẹ pelu iyanrin òkun…


Òjò ṣú biribiri l'ori eti okun ti orun npa

Ojo su biribiri lori okunrin ati obirin.Ó tànmọlẹ

Pelu ìṣírí abo kiniun,

Ó dahun,

Pelu ìtàná ti o wọ bi ẹwu;


Bệni ìjì òkun ntẹlẽ bọwá si bèbè,

Abo kiniun mi,

Ti a de ni ade oṣupa.

Abo kiniun mi pelu ori eyan

Ti a de ni ade Farao.

Awo yèyé Idoto; awo yeye Ọya

Awẹnrẹn Ifá,

Odùṣọ Èlà, iyekan Ẹlẹgbára


Ìrírí rè ko ju iṣẹju akàn lọ-

Ìsáná ti a tan ni iwaju ĕmí ẹfȗfù nla-

Kia mọsa ni iriri yi je pelu jigi ti o yi mi po.Sinu omi…

Awon iji omi ńwĕ, bi o ti ńrì sinu omi;

Wúrà ti o ńwọmi

Lai ko si eniti ti o le kõ jọYemoja inu ibú,

Eti àṣírí ti hù bi ìwo Àlàdé*.

Emi ti emi si wa dáwà nihin,

Bẹrẹsi ka iyanrin ti òkun gbe wa sihin,

Ka ore rè, oba birin mi.Sugbon okun ti o ti wẹwó iji mu òjìjí

Wa lati jigi oju rẹ

Ti kǐ se ti olorì mi, bíkòṣe ojiji ti o ti fón ká.


Idi ni yi ti emi fi nka àkókò ni erékùṣù mi

Ti mo nka wakati ti yio gbe

Obabirin mi ti o pònrá padàwá pelu ami angeli ninu afẹfe
*Ninu iwe Alawiye ti Olȏgbe Odúnjọ kọ a ka itàn Àlàdé ti o hùwo ti ọrẹ re ko le fi sinu. O si lọ gbẹ iho ti ó kigbe pé: Alade huwo. Lehin eyi opolopo iwo nhu bi ohun ọgbin ni agbègbè na.

No comments:

Post a Comment

 
Vida de bombeiro Recipes Informatica Humor Jokes Mensagens Curiosity Saude Video Games Car Blog Animals Diario das Mensagens Eletronica Rei Jesus News Noticias da TV Artesanato Esportes Noticias Atuais Games Pets Career Religion Recreation Business Education Autos Academics Style Television Programming Motosport Humor News The Games Home Downs World News Internet Car Design Entertaimment Celebrities 1001 Games Doctor Pets Net Downs World Enter Jesus Variedade Mensagensr Android Rub Letras Dialogue cosmetics Genexus Car net Só Humor Curiosity Gifs Medical Female American Health Madeira Designer PPS Divertidas Estate Travel Estate Writing Computer Matilde Ocultos Matilde futebolcomnoticias girassol lettheworldturn topdigitalnet Bem amado enjohnny produceideas foodasticos cronicasdoimaginario downloadsdegraca compactandoletras newcuriosidades blogdoarmario arrozinhoii sonasol halfbakedtaters make-it-plain amatha