Enjoy the "sweet" music by a talented youngman
This Year ODUN YI
https://www.youtube.com/watch?v=efMSwiCBIrs
Below, I pray for you in Yoruba. Don't ask me to translate—Ask Professor Pamela Smith, a distinguished member on this list. I was told that the only language God understands is Yoruba!!!!
Iwure Ọdun 2021
Orin:
"Ọdun de!
Ọdun jọ!
Amọdun wa eṣin ko o!
Ọdun de!
Ọdun jọ!
Amọdun wa eṣin ko o!"
Iba Eleduwa!
Iba ẹyin to laye!
Amọdun ta ṣe leṣin wa ko peregede!
A dupe.
Ọba Adẹdaa,
Mariwo ni pe jọ mu'le Ogun dun.
Tutu nini ni t'ile igbin.
Olodumare, je ki ọdun 2021 ko dun fun wa,
Ko tu wa s'ire gbogbo!
Gbogbo igi telegbede ba fọwọ ba,
Didun nii dun!
Bi a ba ta a,
Ka ri i ta ninu ọdun titun!
Bi a ba lu u, ka ri i lu ninu ọdun tuntun!
Kokoro ajakalẹ Korona to gbode aye,
Ko ni rọna ni kaa wa.
Gbogbo ajogun ti dẹburu ọna,
Wọn o ni ri sakani awa!
Ire 'loju owoo ri!
Ka rire lọtun,
Ka rire losi,
Bi a ba kọju siwaju,
Ki ire o maa wọ tuururu bọ l'ọdọ wa!
Bi a ba wehin,
Kire nla o maa wọ tuurutu bọ l'ọdọ wa!
Ire owo!
Ire ọmọ!
Ire aiku baalẹ oro!
Lọtun, lọtun l'ọjọ wa yoo maa yọ ire fun wa o!
Ọdun a yabo;
Ko ni yakọ fun wa o!
Oju wa to r'ipile ọdun nii yoo ropin rẹ o!
A o ṣe pupọ ọdun laye ati laaye ire o!
Edumare to n dari aye yoo gba a bẹẹ fun wa o!
Awọn to laye ko ni pada lẹhin wa o!
Ire gbogbo ko maa kankun tọ wa wa ninu ọdun tuntun!
Orin:
Awa ta n ṣọdun nii la o ṣe tẹẹmi o!
Awa ta n ṣodun nii la o ṣe teemi o!
Awa ta n ṣodun nii la o ṣe teemi oo!
Ọdọọdun la a rorogbo!
Ọdọọdun la a r'ọmọ obi latẹ!
Awa ta a ṣ'ọdun yii la o ṣe teemi o!
A-ṣe-n- ṣe-tun- ṣeee!
No comments:
Post a Comment