Sunday, May 21, 2017

USA Africa Dialogue Series - Ewi Igbokegbodo Keta

Odùṣọ Ifá
Àwọn ìràwọ ti wá rékọjá,

Àwọ sánmà pẹlú awò ojúkan rẹ

Nwòye ayé abẹ rẹ.


Awon ìràwọ ti rekoja,

Ṣùgbọn o, èmi –nibo ni emi wà?

Múra ki o túnramú, ìwòye mi,

Lati dìrọmó wakati yi,

Ki o si mú ileri ìgbà yi ṣẹ

Pelu orin àti ẹyẹ.


Odùṣọ ifá yọ si mi

Gegebi yemọja òkun

Abara rọgbọdọ

O wipe:


Túraká! Ifá kò robi sẹni kan

Kókó ifa ni lati ta ibi nù

Ati lati kó ire wọlé.

Kọlọfin ibi ilà gbé pàdé

Ni oríta Ẹlẹgbára.

Kọlọfin ibi ilà gbé pàdé

Ni àgbélèbú ti paradà di oríta ọnà

Kọlọfin ibi ti Ila gbe pade

Ni bèbè Náìlì tí ọmọ gbẹnọ gbẹnọ

Gbé sọ ẹnọ àmójúbà Ẹlẹgbára;

Kọlọfin ibi ilà gbé pàdé ni Ojú Ẹlẹgba*

Ni olùdándè ojú inu ti o sọnù,

Ti a ṣe ìràpadà rẹ si ìparadà orin kíkọ;

Ilà èkíní ni ti ohùn òkè

Ati ti ìsàlẹ orin alárinrin ni ipasẹ

Gbédègbeyọ Ẹlẹgbára;

Ilà èkejì ni ti òṣùnwọn

Ìgbà mélǒ ni ìlù lílù pẹlú

Irinṣẹ orin Lákáayé pẹlu atọkùn Ọrúnmìlà;

Ni ibi ti ewì gbé paradà

Di ìmọ orin ayérayé…Odùṣọ Ifa t'ẹnu b'orin:

Ẹ má s'Èṣù d'èké

Ẹ ma sọ'fá d'ọlẹ

Kos'ésìn kẹsìn ti o bori ifa.

Odùṣọ, oníbodè ibode Òrun

Ệlà, onílànà ọrọ ìrètí ògo.*Fún ìwòye itumọ Ojú Ẹlẹgba, mo dúpẹ lọwọ ògbóntagí iyèkọn akẹkọ mi, onímọ iṣẹ onà gbólóhùn, Ọjọgbọn Adémọlá Dàsylvà.


No comments:

Post a Comment

 
Vida de bombeiro Recipes Informatica Humor Jokes Mensagens Curiosity Saude Video Games Car Blog Animals Diario das Mensagens Eletronica Rei Jesus News Noticias da TV Artesanato Esportes Noticias Atuais Games Pets Career Religion Recreation Business Education Autos Academics Style Television Programming Motosport Humor News The Games Home Downs World News Internet Car Design Entertaimment Celebrities 1001 Games Doctor Pets Net Downs World Enter Jesus Variedade Mensagensr Android Rub Letras Dialogue cosmetics Genexus Car net Só Humor Curiosity Gifs Medical Female American Health Madeira Designer PPS Divertidas Estate Travel Estate Writing Computer Matilde Ocultos Matilde futebolcomnoticias girassol lettheworldturn topdigitalnet Bem amado enjohnny produceideas foodasticos cronicasdoimaginario downloadsdegraca compactandoletras newcuriosidades blogdoarmario arrozinhoii sonasol halfbakedtaters make-it-plain amatha