V
Olayinka: Àgbà ọjẹ
Kristofa: Hunhn?
Olayinka: Gbogbo iyipada ni láburú ndan?
Kristofa: Ilọsiwaju ní ilana ìṣẹdálẹ ni tiwa.
Olayinka: Olu irin ati Olukoso ti gbakoso ilosiwaju ise orin.
Kristofa ati Olayinka: Awa ke pe awon iṣọwọ ilu to soríkọ
Ti o nwoye:
Kristofa: Lehin ikẹdun àṣà atijọ ti o sorikọ
Olayinka: Ni imurasile fun isodotun.
Kristofa: Iṣọwọ ilu ti o soríkọ kó
gbérasọ
Olayinka: Ohùn apa-ara Olúkòso
Kristofa: Ohùn Olukoso amilẹ jijin
Olayinka: Wa ni ìpamọ si inu okùn
Olu irin.
Kristofa: Gìtá ẹlẹrọ amìnjìnjìn; Kàkàkí
bẹnu gọtìọ
Kristofa ati Olayinka:Apapọ ohun Olukoso
ati Olu irin.
Olayinka: Ohùn Itesiwahu Sita ati Goje
Kristofa: Ìgbésẹ itẹsiwaju Kóra ati Bánjò
Olayinka: Ohùn iranlọwọ fun
Bẹmbẹ ati Àgídìgbo
Kristofa: Ìpohùnréré fun
Ajumoṣe ilu bàtá ati gangan
Olayinka: Ajùmọṣe ṣẹkẹrẹ pẹlú iya ilu
Kristofa ati Olayinka: Isodotun àjọyọ pelu
Orin tuntun…
Kọlọfin ibi ilà gbé pàdé ni Ojú Ẹlẹgba
Ilà èkíní ni ti ohùn òkè
Ati ti ìsàlẹ orin alárinrin ni ipasẹ
Gbédègbeyọ Ẹlẹgbára;
Ilà èkejì ni ti òṣùnwọn
Ìgbà mélǒ ni ìlù lílù pẹlú
Irinṣẹ orin Lákáayé;
Ni ibi ti ewì gbé paradà
Di ìmọ orin ayérayé…
No comments:
Post a Comment